Friday, March 13, 2020

Yorùbá Se Àmúdópin Èètò Lórí Àmòtékùn

Ajíse Bí Ọ̀yọ́ Làárí, Ọ̀yọ́ Kìí Se Bíí Baba Ẹnìkọ́ọ̀kan. Àìrìnpọ̀ ejò níí j'ọmọ ejò níyà tọ́ká bá dúró, tí sèbé dúró, tí paramọ́lẹ̀ náà tún k'ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí, t'éjòlá tíí ṣe baba wọn náà ńwọ́ ruru bọ̀ lẹ́yín wọn, ẹ gbọ́ná, talò tóó gbénà w'ojú ẹkùn láì fòyà?


Níwọ̀nba ìgbà tí ènìyàn bá ti lè jẹ́ ọmọ Odùduwà, ọmọ káàrọ́ọ̀-oòjíire. Àtiwípé, tí olúwa rẹ́ sì tún jẹ́ aṣojú réré fún Yorùbá. Ní ibìyówù tí olúwa rẹ̀ kì báà máa gbé níbikíbi gbogbo orílẹ̀-èdè àgbáyé, nwọ́n sọ wípé, Àmòtékùn ni gbogbo wà.
Àwọn àwòràn wọ̀nyí ni ó ńse àfihàn Gómìnà wa, Amojúẹ̀ro Seyi Makinde, pẹlu àwọn asojú-ṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, níbití nwọ́n ti ńbuwọ́ lùwé òfin ìfilọ́lẹ̀ èètò ojú-lalákàn fíí s'ọ́rí nnì, ÀMÒTÉKÙN.

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìròyìn tó kàn wá lọ́wọ́ ǹfi yéni wípé iṣẹ́ ti nlọ ní ràbàjìgan lọ́wọ́ ní gbogbo ìpínlẹ̀ ìwọ̀orùn yókù, eléyìí tí kòsì yọ ìpínlẹ̀ Kwara silẹ̀ pẹlú.


Bí Yorùbá bá lè máa ṣe báyìí sowọ́pọ̀ láífi t'ẹ̀sìn tàbí t'ósélú se, èrè m̀bẹ fún wa, lẹ́yìn wá ọla.

À ǹfi anfààní eléyìí pe àwọn aṣojú wa pẹlú ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà méjèèjì yókù, láti ṣiṣẹ́ lórí èètò yí pẹlú.


- Olawale

No comments:

Post a Comment